Qdot – Moriamo Lyrics

Qdot Alagbe The Album

Qdot – Alagbe The Album Lyrics

Qdot Moriamo Lyrics

Omo Adefi
Omo Adefa loke Iresi
(Moriamo Alege, Moriamo)

Iya baba mi, sun re
Ni’le aye 1980′ somethin’
(DaBeat Handle)

Damilare, emi l’akobi bami
Ki Qudus toh di Qdot
Iya ati baba mi ti jaa, o ti pe
Kin toh wa’ye, loti ni won le fe’ra won
Okun ebi t’oba jaa, welder kan o le jo (alagbe)
K’Olohun f’orun ke Moriamo, iya baba mi
Moriamo, omo Alege
Iya ma n gb’omo ge ge ni
Mama o gbe mi sile, k’eyan kan kan toju mi
Moriamo, sun re (sun re)
Mi o gbagbe oko Alado l’ona Erugbabu
Oko obi yi Grandma ti foh loju kan
Boya n tori obi toh ma ta ni muri kan
Iya yi tun pada s’oko, ada t’ohun, t’oko ni
Ori mi a wu, toh ba pe ni “oko mi”
Ojo ri je pelu ojo riri mu
Mama ma n r’oka pelu Efo Bokolu
Omi odo la ma n mu
L’abule Ado, l’abule Ado oh (abule Ado)
Abule wa o jina si Shagamu
A n pada s’oko ni motor jam, o ma shee
Mama ba n pariwo “Damilare, omolomo ni, e ba n gbe”
O ma shee (o ma shee)
Ojo yen ni mo mo pe iya yi ko lo bi mi

Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege (Moria oh)
Moriamo Alege
Iya baba mi, orun re e
Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege (Moria oh)
Moriamo Alege
Iya baba mi, orun re e, orun re e

Hmm, ojo re bi ana nigba t’iku wole de
Iya yi ti r’iku loshey ni n b’ode na
K’oju mi ma ba r’ibi
Rafiu, aburo mi n gba boolu nita
Mo wo’le pada, mama ti d’oju bo’le
Kayeefi loje, mo saare pe baba mi
“Adio, o wa dakun wa wo mama re?”
A shey olojo lode oh
Ngba t’ariwo ta lowo mi n wa kilode
Kin toh mo, ese ti pe
Shifau pelu Mutairu beree si nke (omije oh)
Won ni “won o le sin mama”
Moni kilode?
Won ni “emi o jade tan” (ahh)
Kofe fimi sile loh ni
Ojo ‘kini lo, ikeji loh
Ojo ‘keta, Moria dagbere fun’aye

Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege (Moria oh)
Moriamo Alege
Iya baba mi, orun re e
Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege
Iya baba mi, orun re e, orun re e (Moriamo, Moriamo oh)

Moria dagbere fun’aye
Odi’gba, odi’gbere (Moriamo)
Mama Shifau, mama Mutairu
Moriamo omo Alege, orun re e (Moriamo)
Ma ro’yin f’omo mi (Moriamo oh)
Moriamo, Moriamo oh (Moriamo)
Moriamo (Moriamo Alege)
Ayy-ayy-ayy
Yeah, who’s here?

Written by; Qdot
Released date; 17 November, 2020
Album/EP; Alagbe The Album

Moriamo Lyrics Qdot