Brymo – Ọkùnrin Mẹ́ta (Ẹ̀dùn Ọkàn) Lyrics - FindOutLyrics Brymo – Ọkùnrin Mẹ́ta (Ẹ̀dùn Ọkàn) Lyrics - FindOutLyrics

Brymo – Ọkùnrin Mẹ́ta (Ẹ̀dùn Ọkàn) Lyrics

Brymo Ọkùnrin Mẹ́ta Lyrics, Ọkùnrin Mẹ́ta Lyrics by Brymo, Brymo Ẹ̀dùn Ọkàn Lyrics, Brymo Ọkùnrin Mẹ́ta Lyrics English Translation

Gbémi ṣán lẹ̀
Kó mi sí’ta
Fàmí lẹ’wù ya
Tẹ̀mí lọ́rùn pa
Ènìyàn lásán ni mo jẹ́
Mo fú’yẹ́ bíi paper
Ìjí jà lódò
Ó gbémi lọ sóko

Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l’ọkọ̀
Gbé mi lọ síbi tó kàn
Ògá tà ògá ò tà
Ọlọ’ọ’pá gba rìbá kàsà
Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l’ọkọ̀
Gbé mi lọ ibi mò ń lọ
Ẹ̀dùn ọkàn
Fún mi lọ́kàn
Ọkùnrin mẹ́ta dé’bi tí mò ń lọ

Èmi ni ìmọ́lẹ̀
O ló’kùnkùn wọ gbó lọ
Mo fà á lẹ́’wù ya
Mo tẹ̀ l’ọ́rùn pa
Ènìyàn lásán mi ò jẹ́
Mo wíwo bí ẹ̀san
Èmi ni ìjì tó jà l’ódò
Tó gb’ọba wọn lọ s’óko

Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l’ọkọ̀
Gbé mi lọ síbi tó kàn
Ògá tà ògá ò tà
Ọlọ’ọ’pá gba rìbá kàsà
Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l’ọkọ̀
Gbé mi lọ ibi mò ń lọ
Ẹ̀dùn ọkàn
Fún mi lọ́kàn
Ọkùnrin mẹ́ta dé’bi tí mò ń lọ

Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l’ọkọ̀
Gbé mi lọ síbi tó kàn
Ògá tà ògá ò tà
Ọkùnrin mẹ́ta dé’bi tí mò n lọ