K1 De Ultimate Awùjalẹ̀ Lyrics, K1 De Ultimate Awujale Lyrics
Thank you God almighty
Èyí tó o ṣe fún bàbá wa
Aláyélúwà Kábíèsí Ọba SK Adétọ̀nà òrìṣà Ìjẹ̀bú
Ọ̀gbágbá the second
Awùjalẹ̀ of Ìjẹ̀bú land at 90
And 65 years on the throne still counting
A mọ̀ọ́ lóore Ọlọ́hun
Ọlọ́hun bá wa ṣe ìkẹ́ ìgẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà
Ká rí bàbá wa pẹ́ Àmín Ọlọ́hun
Èèyàn tó bá wu Ọlọ́hun Sati ló ń dá lọlá
Ni mo ṣe dúpẹ́ Ọlọ́hun arábámbí
K1 De Ultimate Àyìndé lórí Kábíèsí Awùjalẹ̀ baàmi
Ọmọ ológbò sá gìrìgìrì lọ́jà
Àìtètè gbọ́n ológbò ló ń jìyà
Bó bá pẹ́ títí á tó eku pa jẹ
Fún tọjọ́ ìbí bàbá mi Aníkinláyà saàgùn o
Èrò tí ń lọ sí Mushin ẹ kí wọn ní Mushin
Èrò tí ń lọ sí Sókótó ẹ kí wọn ní Sókótó
Èrò tí ń lọ sí ilẹ̀ Kano o ẹ kí wọn ní ilẹ̀ Kano o
Èrò tó ń bọ̀ l’Olúyọ̀lé o Fìjàbí onílẹ̀ obì ńkọ́
L’ákilẹ̀ Ìjẹ̀bú Awùjalẹ̀ ló nilẹ̀ o
Aládé àlàáfíà Awùjalẹ̀ ló nilẹ̀ o
Adúpẹ́ fún Olúwa bàbá wa ṣe 90
His Royal Majesty Ọba SK Adétọ̀nà Aládé àlàáfíà
Bàbá mi ẹ̀mí yín á ṣe púpọ̀ o
65 lórí àléfà still counting
Ọ̀gbágbá Adétọ̀nà aníkinláyà Saàgùn
Ọkọ ti Ìyábọ̀dé olorì ọkọ ayaba olorì Kẹ́mi o
Bàbá Adédire bàbá Adétutù
Bàbá Adénìkẹ́ o bàbá Adérónkẹ́ mi
Bàbá ti Adébìyí o bàbá Adéníyì
Bàbá Adétóún mo kí Ọba
Bàbá K1 De Ultimate
Olórí ọmọ’ba níjẹ̀bú òòṣà Ìjẹ̀bú aníkinláyà
Baàmi Aníkinláyà saàgùn
Ọlọ́hun ló bá wa ṣé
Mo dúpẹ́ Ọlọ́hun o
Bàbá mi l’aládé àlàáfíà
Òun ni kìnnìún Judah
Ọ̀rọ̀ mi Àyìndé Wasiu
Ìtàn ìgbésí ayé mi
Ọmọ Síkírù méjì
Ìkan Déyímiká Barrister
Ló gbé Fújì fún mi
Ni mo ṣe ń jó mo ṣe ń yọ̀
Aládé àlàáfíà SK Adétọ̀nà
Bàbá mi ló ró mi láṣọ
Wọ́n ní kí Àyìndé gba double
Ọ̀túnba fìdípọ̀tẹ̀ mọ́lẹ̀
Àti olórí ọmọ Ọba níjẹ̀bú
Ah ṣé ẹ rí ilé ayé mi
Ẹ wo ohun ti bàbá ṣe ò
Fún adé orí ọ̀kín
Ìsẹ́yìn ni inú mi dùn
Olúayé Fújì
Ọlọ́hun Ọba ló bá mi ṣé
Ọmọ Alimo Sadia
Ọkọ Àjíkẹ́ ẹlẹ́bà yellow
Ayaba red lips mi
Ọlá bàbá Sule bàbá Basira mi lawyer
Bàbá Amari mi Fatimo
Bàbá Ọláńrewájú Halima
Bàbá ti Àńjọláolúwa Àbíkẹ́ adé
Àyìndé bàbá Adédiwúrà
Bàbá ti Àkànkẹ́ Melissa mo ki kira mi
Ah yí ọ́ da fún ọ tí ọ́ pọ̀
Fìdípọ̀tẹ̀ níjẹ̀bú òde owó Bàbá Fẹ́mi
Olórí ọmọ Ọba níjẹ̀bú
Ṣé ẹ rí adé orí ọ̀kín
Ṣé ẹ rí adé orí ọ̀kín
Ṣé ẹ rí adé orí okin
Ṣé ẹ rí adé orí ọ̀kín
2025 tí wọ́n ń sọ o
Olókun ń gbọ́ ọlọ́ṣà ń gbọ́
Ọdún tá a wí ti dé
2025 tí wọ́n ń sọ
Àsìkò Tinubú mà la wà
Gbogbo ọmọ ṣiṣẹ́ṣiṣẹ́ àpamọ́wọ́ owó wa
Bẹ́ ẹ bá rán owó kékeré ńṣẹ́ ńlá ni ó padà
Gbogbo ọmọ ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́
Nínú ọdún yìí ratio one to three
Àní àpamọ́wọ́ owó wa ò
Gbogbo ẹni tó ń wojú Olúwa
Ó ma rí àánú gbà
Á dẹ̀ báwa d’ọjọ́ alẹ́ bó w’ọlá Ọlọ́hun o
Torí ọdún owó ti dé
2025 tí wọ́n ń sọ
Ẹ lu àlùjó gbẹ́sẹ̀
Mo ní ẹ lu àlùjó gbẹ́sẹ̀
Ẹ ganu sí Fújì mi
Ẹ lu àlùjó gbẹ́sẹ̀
(Ẹ ganu sí Fújì mi)
Gbẹ́sẹ̀
Gbẹ́sẹ̀
Gbẹ́sẹ̀
Gbẹ́sẹ̀ sókè
Ẹ lu àlùjó gbẹ́sẹ̀
(Ẹ ganu sí Fújì mi)
Àlùjó gbẹ́sẹ̀
Ẹ lu àlùjó gbẹ́sẹ̀
(Ẹ ganu sí Fújì mi)
Ah ah àlùjó gbẹ́sẹ̀
(Ẹ ganu sí Fújì mi)
Gbẹ́sẹ̀
Gbẹ́sẹ̀
Gbẹ́sẹ̀
Gbẹ́sẹ̀ sókè
Àlùjó gbẹ́sẹ̀
(Ẹ ganu sí Fújì mi)
