K1 De Ultimate Ayé Digital Lyrics, K1 De Ultimate Aye Digital Lyrics
Fújì music is taking you
Let’s go there man
Ọlọ́hun ló ṣe agbára mo gbé títóbi fún Ọlọ́hun
Ó ṣe agbára fún wa a lò le kó wọn dànù
Ọlọ́hun ló lágbára mo gbé títóbi fún Ọlọ́hun
Ó ṣe agbára fún wa a ò le kó wọn dání
Ògún is a iron
Ṣàngó is a fire
Ará is a thunder
Ifá is divinity
Ọlọ́hun ló lagbára mo gbé títóbi fún Ọlọ́hun
Ó ṣe agbára fún wa a ò le kó wọn dání
Ẹni tó bá ní tọlọ́hun báwo ni
Wọ́n á jìyà wọ́n á jẹ ewé iyá mọ
Láti ayé níbí títí lọ sọ́run wọn ò mọ ìyẹn
Ògún is a iron
Ṣàngó is a fire
Àrá is a thunder
Ifá is divinity
Ọlọ́hun ló lagbára mo gbé títóbi fún Ọlọ́hun
Ó ṣe agbára fún wa a ò le kó wọn dání
Ọmọ Ojúṣàágbọlá ọ̀gọ́jì ṣá ni mí
Ọmọ òkóbì fún o#ìkà o
Kí òṣìkà fi ẹnu ẹ̀ wúre nílé bàbá mi
Afìdípọ̀tẹ̀mọ́lẹ̀ níjẹ̀bú òde
Ọmọ Ọba lọ́tùn-ún lósì ni mí ọmọ Anífowóṣe
Láti Ìjẹ̀bú lọ sí Èkìtì ní ìlú Ìlúpéjú
Ọmọ ọmọ Akérédolú mi Àyìndé
(Islamic rendition)
K1 De Ultimate
(Ayé digital la wà Classical Fújì)
Ọmọdé yìí ó ń jó
Ọmọdé yìí ó ń jó
Ọmọdé yìí ó ń jó
Ó ń ṣèdí pa pa pa pa pa pa pa pa
Ó ń ṣèdí pa pa pa pa pa pa pa pa
Don’t spread your legs
Má tẹ́rí si
…
Al Afeez Àdìsá ìgbẹ́ṣẹ́ Balógun máa gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Ni mo ṣe kọjá lọ sí Oṣòdì Arábámbí
Aircraft Engineer ọkọ late Monsuratu Mosúnmọ́lá
Àṣàbí adé ọmọ Raji
Raji Àtàndá mi níbàdàn o ṣé
Ọmọ Alhaji Raheem mi Àtàndá adé
Olórí ẹlẹ́ran ìjàyè òbírìjì gbágùrá lábẹ́ olúmọ ní Ẹ̀gbá ilé
Ọmọ Alhaja Ramotalahi Àjíún
Ọmọ ọmọ Akínboyè mi òyìnbó aláṣọ
Ọ̀rẹ́ Senate leader mi Ọpẹ́yẹmí
Ọmọ Bámidélé ọ̀rẹ́ Al Akeem ọmọ agbára tírà mi
Ọ̀rẹ́ ti Ibrahim Soliu ọmọ olówo
Too much money mi ọkọ Mudira
Ọ̀rẹ́ Honourable Moruf ọmọ Akíndẹrù mi
Gbogbo ẹ̀yin leader l’Óṣòdì
K1 De Ultimate mo ki yín
Arábámbí mi Àyìndé o
Ìpẹ̀ ṣá ni leader (leader ni)
Afeez Ìpẹ̀ ṣá ni leader (leader ni)
Ọmọ ti Aṣíwájú mi leader (leader ni)
Awon ti Oṣòdì wọ́n ní n kí ẹ o (leader ni)
Bàbá ti Àyìndé mi Musiliu (Egúngún Ayédáadé)
Bàbá ti Àyìndé mi Musiliu (Egúngún Ayédáadé)
Afeez Ìpẹ́ṣá Balógun (leader ni)
Leader leader leader leader
Afeez Ìpẹ̀ṣá Balógun (Ìpẹ̀ṣá Balógun)
Gbogbo èrò tó ń lọ sí Oshodi
Ẹ bá mi ki Ìpẹ̀ṣá Balógun (Ìpẹ̀ṣá Balógun)
Al Afeez awọ ti Àyìndé olókùnọlà (Ìpẹ̀ṣá Balógun)
