K1 De Ultimate Better Dey Come Lyrics

Àyìndé ti gb’órin ẹ̀ dé o o o
Aláyìndé ti gbé orin ẹ̀ dé o
Àyìndé ti gbé orin ẹ̀ dé o o o
Ọba Fújì ti gbé orin ẹ̀ dé o
Orí classical ṣá la wà o
Ẹ wo bó ṣe ń pèdè bí ẹní láyin
Ẹ wo bó ṣe ń pèdè bí ẹní jiyọ̀ o
Ọba Fújì ti gbé orin ẹ dé o

Better dey come o better dey come
Àní better dey come o ọ̀la ń bọ̀ wá dára
Ó ń bọ̀ wá dára o má ṣe sọ ìrètí nù o
Better dey come o better dey come
Mo ní better dey come o ọ̀la ń bọ̀ wá dára
Ó ń bọ̀ wá dára o gbogbo ọmọ Nigeria
Láti ìgbà òmìnira nǹkan ò gún régé
Ẹ̀bẹ̀ là ń bẹ aláwùrà ṣíjú wo ọ̀rọ̀ Nàìjíríà o
Amẹ́ríkà tí à ń sáré lọ o wọ́n ń forí la ikú
Germany tí à ń sáré lọ o wọ́n ń f’orí lakú
South Africa tí à ń sáré lọ o wọ́n ń forí la ikú
Ní ìgbà tó dára fún wọn o là ń sọ ọ̀rọ̀ Canada o
Better dey come o better dey come
Àní better dey come o ọ̀la ń bọ̀ wá dára
Ó ń bọ̀ wá dára o má ṣe sọ ìrètí nù o
Ó ń bọ̀ wá
Ó ń bọ̀ wá
Ó ń bọ̀ wá better
Tí Yorùbá ti Ibo pẹ̀lú Hausa
Pikin do your own o ó ń bọ̀ wá

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ tó dára jù arábámbí
Ẹ jẹ́ kí everybody ó dáko ọ̀rọ̀ nìyẹn
(Owó tó pọ̀ la máa rí o )
(Eh eh eh eh)
(Owó tó pọ̀ la máa rí)
O sure jù bí everybody bá dáko
(Owó tó pọ̀ la máa rí o )
(Owó tó pọ̀ la máa rí)

Ẹ̀yin tèmi ẹ lọ mú sùúrù
(Ó ṣì máa dára lọ́lá Ọlọ́hun)
Ẹ̀yin tèmi ẹ lọ mú sùúrù
(Ó ṣì máa dára lọ́lá Ọlọ́hun)
Gbogbo gbèjò gbèjò tó bá mú sùúrù
(Á kún garawa lọ́jọ́ ọjọ́ kan àfàìrọ̀ òjò)
Ọ̀rọ̀ yìí ò f’àjà b’a bá mú sùúrù
(Ó ṣì máa dára lọ́lá Ọlọ́hun)

Abíọ́lá Ayélàágbé mo kí ẹ sílé
Àdùnní Abisco Abíọ́lá mother ti Àánúolúwamípọ̀ yìí o ṣé
Oro nilé ní Kwara o
Ọmọ wọn ní ilé Àró
Bíọ́lá mo kí ẹ kí ẹ aláṣẹ Kunlex Abisco Nigeria Limited
Àdúà ẹ ti gbà Abíọ́lá
Ọmọ ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́ mi tí Ọlọ́hun Ọbá gbà fún
Yí ọ́ da fún ọ tí ọ́ pọ̀ Abíọ́lá Òro nílùú Kwara ni
Òyìnbó oní DHL Nylons
Òyìnbó oní packaging Nylon bags
Òyìnbó oní fancy nylons
Bíọ́lá Dòsùnmú lọmọ wà tó ń pawó ajé
Eeyan tèmi Adégoróyè aya Ayélagbé
Mo kí ẹ kí ẹ baby Bíọ́lá
Ọlọ́hun ló f’èrè s’ọ́jà ẹ Abíọ́lá
Kò ní sú ẹ ṣe Àmín àṣẹ
Dòsùnmú lọmọ́ wà (Bíọ́lá baby)
Dòsùnmú lọmọ́ wà o (tó ń pawó ajé)
Bíọ́lá Ayélàágbé mi o
Mother ti Àánúolúwamípọ̀ (Bíọ́lá baby)
Orí la fi ń m’ẹ́ran láwo Bíọ́lá Ayélàágbé
Ẹní ṣiṣẹ́ ló ń lówó Àyìndé èmi mọ (Bíọ́lá Ayélàágbé)
Mo gbe fún ẹ Bíọ́lá Baby mi (Ayélàágbé)
Sister ló jẹ́ fún Ọ̀túnba Yínká mi Quadri (Bíọ́lá baby)

Kábíèsí Òro mo ki yín sílé
Ìbà ẹ ni mo ṣe Ọba Joel Ọyátóyè mi
Adé á pẹ́ lórí bàtà á sì pẹ́ lẹ́sẹ̀ Ọba
Olúfáyọ̀ ìgbà ẹ á tù wá lára Àmín àṣẹ
Olóròó Kábíèsí ẹ Àyìndé o
Baàmi Ìṣọ̀lá Kàmọ́rù mo ki yín sílé
Ọmọ Anímáṣahun Ọlọ́jà ti ìlú Ẹ̀pẹ́ o
Ẹ̀míi yín á ṣe púpọ̀ ọdún láyé
Happy 80th Birthday Bàbá mi olówó Ẹ̀pẹ́
Adé á pẹ́ lórí ẹ baàmi
Ọkọ Ṣubúọ́lá olorì mo ki yín
Ọlá bàbá Àrẹ̀mọ Muhideen mi
Àna Ṣàgẹ̀núwà ní Ọ̀gbẹ̀rẹ̀ torí Bùkọ́lá
Bàbá Wajadina Suhura Ọlátánwá
Bàbá ń pàṣẹ ọmọ ẹ̀ ń pàṣẹ o
Suhura aláṣẹ ìjọba Ẹ̀pẹ́
Ọmọ ti aìṣọ̀lá ọlọ́jà ti Ẹ̀pẹ́ o
Bàbá Idirisu mi Ìṣọ̀lá adé
Owó bàbá ti Al Akeem bàbá Ọmọtógbọ́láhàn mi ọmọ Ọba
Ọkọ Adùnọlá baby mi níjẹ̀bú ayépé
Owó bàbá ti ìbẹta Kábíèsí adé á pẹ́ lórí ẹ Ìṣọ̀lá mi Kamaru mi
Baàmi Ìṣọ̀lá Kàmọ́rù (Ọlọ́jà Ẹ̀pẹ́)
Ìṣọ̀lá mo kí ẹ o (Ọlọ́jà Ẹ̀pẹ́)
Happy 80th bàbá mi ẹ̀mí i yín á ṣe púpọ̀ (Ọlọ́jà Ẹ̀pẹ́)
Ọ̀pọ̀ ọmọ àti àwọn ọmọ ọmọ ni wọ́n ní n k’Ọ́ba (Ọlọ́jà Ẹ̀pẹ́)
Ọ̀túnba Ọlámilékan ní n ki yín
Adéṣẹ̀mọ́wọ́ Olóòtú ọlọ́wọ́ ọkọ kọ́lá
Ó mà ní n kí Ọba Ìṣọ̀lá adé
Chief Madasa Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú Olú òṣùgbó ọlọ́wọ́
Ọmọ Kábíèsí Awùjalẹ̀ ní n ki yín
Ìṣọ̀lá Kàmọ́rù (ọlọ́jà Ẹ̀pẹ́)
Arolúgbadé mo k’Ọ́ba (Ọlọ́jà ẹ̀pẹ́)
Baàmi Ìṣọ̀lá Kàmọ́rù (Ọlọ́jà Ẹ̀pẹ́)
Bàbá Wajadina Suhura (Ọlọ́jà Ẹ̀pẹ́)
Baàmi bàbá Ọmọ́gbọ́láhàn (ọlọ́jà Ẹ̀pẹ́)
Owó Bàbá Idirisu
Bàbá ti Àyìndé Wasiu (olórí ọmọ Ọba níjẹ̀bú)
Balógun ìlú Ẹ̀pẹ́ Honourable Tọ̀gùn
Owó ọkọ Rasakat Rasakat ọmọ Imam àgbà Ẹ̀pẹ́
Ó ní n k’Ọ́ba
Ẹ̀bùn ní n k’Ọ́ba
Àdùnní mi Tairatu
Yéwándé ní n k’Ọ́ba
Àdùnní ọ̀rẹ́ Wajadina Suhura
(Wọ́n ní a kú ọdún)