K1 De Ultimate Àyìndé Lyrics, K1 De Ultimate Ayinde Lyrics
Ah ah ah
Let’s go (there)
Àyìndé ti dé àlàáfíà ti dé o
Àsìkò Fújì vibes ó yá
(Allah Allah yá a ṣẹ Allah Ọba Fújì ti gbéré dé)
(Allah Allah yá a ṣẹ Allah Ọba Fújì ti gbéré dé)
O ò gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Aláyìndé ti dé
Àlàáfíà ti dé o
Ìrọ̀rùn ti dé
Àsìkò Fújì vibes ó yá
(Allah Allah yá a ṣẹ Allah Ọba Fújì ti gbéré dé)
Owó ń bọ̀ owó ń bọ̀ fún ẹni tí ò ní
Ọlá ń bọ̀ ọlá ń bọ̀ to bá ti nífbàgbọ́ o
Ire ń bọ̀ ire ń bọ̀ fún ẹni tí ò ní
Ọlá ń bọ̀ ọlá ń bọ̀ bo bá ti ní ìgbàgbọ́ o
Gbogbo ohun to bá ń fẹ́ Aláyìndé o
Wo ọ̀rọ̀ tèmi Adégoróyè ko fi tọrọ
Wò mí Ọmọ́gbọ́láhàn Àyìndé
Àlàáfíà ti dé o àní ìrọ̀rùn ti dé o
Àsìkò Fújì vibes ó yá
(Allah Allah yá a ṣẹ Allah Ọba Fújì ti gbéré dé)
Ọ̀dọ́mọdé àti alàgbà tani ẹ pé ẹ wá wá
(Eh Wasiu Àyìndé o)
Ọmọ kékèké inú àdúgbò tani ẹ pé ẹ wá wá
(Eh Wasiu Àyìndé o)
Ẹ̀yin Wúńdíá àti adélébọ̀ tani ẹ pé ẹ wá wá
(Eh Wasiu Àyìndé o)
Àgàràú area ni ibi a gbé ti gbé eré wá
(Eh Wasiu Àyìndé o)
Wasiu Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn mi o ọmọ Abíṣoríire
Ìràwọ̀ mi ìràwọ̀ mi o
Ayé ẹ má mà bà á jẹ́
Kúkúǹdùkú o ó ń ṣ’ewé gbẹ̀rugbẹ̀ru
Ọba ló ń fi’ṣẹ́ yinni
Ìràwọ̀ mi Ìràwọ̀ mi o
(Orí suku na n biya)
(Wọ́n pe Àyìndé la wà si lórí)
(Aráyé ń fẹ́ wa)
(Àyìndé làwá wà)
Ọ̀dọ́mọdé àti alàgbà tani ẹ pé ẹ wá wá
(Eh Wasiu Àyìndé o)
Ọmọ kékèké inú àdúgbò tani ẹ pé ẹ wá wá
(Eh Wasiu Àyìndé o)
Ẹ̀yin Wúńdíá àti adélébọ̀ tani ẹ pé ẹ wá wá
(Eh Wasiu Àyìndé o)
Àgàràú area ni ibi a gbé ti gbé eré wá
(Eh Wasiu Àyìndé o)
Ẹni tó wu Ọlọ́hun ló ń dé ládé ògo
Ẹni tó wu Ọlọ́hun ló ń dé ládé ògo
Àní ẹni tó wu Ọlọ́hun ló ń dé ládé ògo
Ẹni tó wu Ọlọ́hun ló ń dé ládé ògo
