K1 De Ultimate Já Ìtàná Lyrics, K1 De Ultimate Ja Itana Lyrics
Arábámbí
Ẹ gbọ́’hun tí òbí ń sọ ẹ̀yin ọmọdé agídí ò dà nǹkan kan
Ẹ gbọ́’hun tí òbí ń sọ ẹ̀yin ọmọdé
Àní agídí ò da nǹkan kan
Ẹ gbọ́’hun tí òbí ń sọ ẹ̀yin ọmọdé
Torí mo rántí ìgbà kékeré mi
Mo mà rántí ìgbà kékeré mi
Bí n bá ń ka poem lọ́jọ́ ọjọ́un
Bí Bàbá mi pẹ̀lú màmá mi
Bí wọ́n bá pè mí pẹ́rẹ́n ma sáré lọ dá won lóhùn
Bí wọ́n bá dẹ̀ ń sọ̀rọ̀ mi ò jẹ́ gbó wọn lẹ́nu
Bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ o
Mi ò jẹ́ gbó wọn lẹ́nu
Ma káwọ́ mi seẹ́yìn ma tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ gbọ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ
Irú ọmọ bẹ́ẹ̀ òun ló yẹ ká jẹ́
Ọmọ alálùbáríkà tó gbọ́rọ̀ òbí
Bí i Tajudeen Fọlá Adéọlá
Tó gbọ́ t’òbí ẹ tó d’olóríire
Já ìtàná tó ń tàn èyí t’ọ́mọdé ń já
(Tó tutù tó sì dára o, já ìtàná tó ń tàn)
Já ìtàná tó ń tàn èyí t’ọ́mọdé ń já
(Tó tutù tó sì dára o, já ìtàná tó ń tàn)
Ẹ̀yin èwe ìwòyí ẹ fi èyí ṣe example
Torí ọmọdé èní àgbà ni lọ́la
Ẹyin ló ń dàkùkọ ẹ̀yin ará mi
Àní ẹyin ló ń d’àkùkọ ẹ̀yin ará mi
Ọmọ tí ò gbọ́ tòbí tí ò ní àánú òbí lójú
Mo bẹ Ọlọ́hun Sati kò ní kọ ọ́ fún wa
Ẹ̀yin òbí o ẹ má sọ ọ̀rọ̀ òdì sí àwọn ọmọ wa mọ́
Torí orí ahọ́n ni àṣẹ wà a ò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ òdì
Àní ká má sọ̀rọ̀ òdì sí àwọn ọmọ wa mọ́
Òbí tó bá ń bú ọmọ ní olòṣì olórí burúkú
Kí wá ni àǹfààní gbogbo wàhálà wa
Wàhálà wa lórí ọmọ
Bí a bá ń b’ọ́mọ wí àdúà ni ká máa fi ẹnu wa ṣe
Awon ọmọ tí à ń wí
Wọ́n á ya dáadáa mọ́ wa lọ́wọ́
Bí a bá ti fi àdúà tìí o
Àmín o
Àmín o
Àmín o
Wọ́n á ya dáadáa mọ́ wa lọ́wọ́
Tí a bá ti fi àdúà tìí o
Àyìndé mo wí tèmi
Mo wí tó tó tó tó tó tó tó tó
Já ìtàná tó ń tàn èyí t’ọ́mọdé ń já
(Tó tutù tó sì dára o, já ìtàná tó ń tàn)
Já ìtàná tó ń tàn èyí t’ọ́mọdé ń já
(Tó tutù tó sì dára o, já ìtàná tó ń tàn)
Ọlọ́hun tó ń dáàbò bo ẹ̀dá o
Mo fi àwọn ọmọ mi lé ẹ lọ́wọ́
Mo bẹ̀ ẹ́ Elédùmarè jẹ́ kí wọ́n máa ṣe dáadáa
Kí wọ́n mú inú wa dùn lójoojúmọ́
A ò ní sunkún lórí ọmọ o Amina
Já ìtàná tó ń tàn èyí t’ọ́mọdé ń já
(Tó tutù tó sì dára o, já ìtàná tó ń tàn)
Bàbá Jazakallahu Khairan Jazakallahu Khairan
(Iba Aira Jazakallahu Khairan)
Arábámbí Jazakallahu Khairan Jazakallahu Khairan
(Iba Aira Jazakallahu Khairan)
Bàbá Jazakallahu Khairan Jazakallahu Khairan
(Iba Aira Jazakallahu Khairan)
Arábámbí Jazakallahu Khairan Jazakallahu Khairan
(Iba Aira Jazakallahu Khairan)
